Jump to content

Ìṣírò

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Arithmetic)
Tábìlì ìsirò

Isiro

Awoyemi, Jolaoluwa

AWÓYẸMÍ JỌLÁOLÚWA

ÌṢIRÒ

Àwọn Yorùbá ní ọ̀nà tí wọn ń gbà ṣe ìsirọ̀, bẹ́ẹ̀ ní àti ọmọkékeré ní àwọn Yorùbá ti ń kọ́ ọmọ wọn ni ìṣirò ní ṣíṣe. Wọn yóò ni kí ó máa fi ení, èjì kọrin, ṣere bíi

Ení bí ení ni ọmọde ńkawó

Èjì bí èjì ni àgbàlà ń tayò

Ẹ̀ta bi ẹta ẹ jẹ́ ka tárawa lọ́rẹ

Ayò tí ta náà tún jẹ́ ọ̀nà tí àwọn Yorùbá fi máa ń kọ ìṣirò Yorùbá ni àwọn ọ̀nà tí wọ́n fi ń ṣe ìsirò wọn fún àpẹẹrẹ “lé”, “dín”, “àádọ́”, “ẹ̀ẹ́dẹ́”, - jẹ́ àwọn ọ̀nà fún ìfilé àti ìyokúrò ìṣirò wọn.

Apẹẹrẹ ìṣirò Yorùbá

1 - óókan

10 - ẹ̀wá

20 - ogún

21 - Ọ̀kàn lè lógún (20+1 = ọ̀kan lé ni ogún)

26 - ẹ̀rìndínlọ́gbọ̀n (30-4 = Ọgbọ̀n dín mẹ́rin)

30 - Ọgbọ̀n

40 - Ogójì (20x2 = Ogún méjì)

60 - Ọgọ́ta (20x3 ogún mẹ́ta)

100 - Ọgọ́rùn-ún (20x5) = Ogún lọ́nà márùn-ún)

120 - Ọgọ́fà (20x6 = Ogún lọ́nà mẹ́fà)

50 - àádọ́ta (20 x3 = 10, ẹ́wàá dín nínú ogún mẹ́ta)

200 - Igba

240 - Òjìlélúgba (40+200; Òjì = 40)

300 - Ọ̀ọ́dúnrún

340 - Ọ̀tàdín nírinwó (400-60 = ọ̀tà = 60 lọ́gbọ́ta)

800 - Ẹgbẹ̀rin (igba mẹrin 200x4)

900 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún (1000-100 = Ọgọ́rùn-ún dín ni Ẹgbẹ̀rún

1000 - Ẹgbẹ̀rún

1600 - Ẹgbẹ̀jọ (200x8 = igba méjọ

2000 - Ẹgbẹ̀wàa (ẹgbàá) (200x10 – igba ní ọ̀nà mẹ́wàá)

4000 - Ẹgbàajì (2000x2)

6000 - Ẹgbàata (2000x3)

7000 - Ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (8000-100 = Ọgọ́rùn-ún, dín nínú Ẹgbàárin (800)

10, 000 - Ẹgbàarùn-ún (Ẹgbẹ̀rùn-ún àádọ́ta ẹgbẹ̀rùn-ún - àádọ́ta ọ̀kẹ́).

Awon iye tabi nọ́mbà lati 1 - 1,000,000,000 (Ọkan si egbélégbè ati àìníye)[1]

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Awa nilo ranti pé a ni orisirisi ona lati awon iye, apeere je 230, ni ede Yoruba e le so "ojì-din-lẹwá-lé-nígba" tabi " Ọgbọnwolerugba"[1]

0 - Òdo

1 - Ọkàn

2 - Méjì

3 - Mẹ́ta

4 - Mẹ́rin

5 - Márùn

6 - Mẹ́fà

7 - Méje

8 - Mẹ́jọ

9 - Mẹ́sàn

10 - Mẹ́wàá

11 - Mọ́kànlá

12 - Méjìlá

13 - Mẹ́tàlá

14 - Mẹ́rìnlá

15 - mẹ́ẹ̀ẹ́dógún / Marundinlogun

16 - Mẹ́rìndínlógún

17 - Mẹ́tà-dínlógún

18 - Méjì-dínlógún

19 - Mọ́kàn-dínlógún

20 - Ogún

21 - Ọkànlélógún

22 - Méjìlélógún

23 - Mẹ́tàlélógún

24 - Mẹ́rìnlélógún

25 - Marundinlogbon / Mẹẹdọ́gbọ̀n

26 - Mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n

27 - Mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n

28 - Méjì-dínlọ́gbọ̀n

29 - Mọ́kàn-dínlọ́gbọ̀n

30 - Ọgbọ́n

40 - Ogójì

50 - Àádọ́ta

60 - Ọgọ́ta

70 - Àádọ́rin

80 - Ọgọrin

90 - Àádọ́rùn

100 - Ọgọ́rùn  

110 - Àádọfà

120 - Ọgọfà

130 - Àádóje

140 - Ọgóje

150 - Àádójo

160 - Ọgọjọ

170 - àádọ́sàn / àádọ́sàn án / Igba kan ó-dinógbòn[1]

180 - Ọgọsàn- / Ọgọsàn-án

190 - àádọ́wá

200 - Igba

300 - ọ̀ọ́dúnrún

400 - Irínwó

500 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta

600 - ẹgbẹ̀ta

700 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin

800 - ẹgbẹ̀rin

900 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún

1,000 - ẹgbẹ̀rún

2,000 - ẹgbàá

3,000 - ẹgbẹ̀ẹ́dógún

4,000 - ẹgbàajì

5,000 - ẹgbẹ̀rún márùn-ún / ẹgbẹ̀rún márùn

6,000 - ẹgbẹ̀ta

7,000 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin

8,000 - ẹgbàá-mẹ́rin

9,000 - ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárún

10,000 - ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá / ẹgbàarùn-ún

20,000 - ọ̀kẹ́ / ẹgbàáwá

100,000 - ọ̀kẹ́ márùn-ún / ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn-ún

200,000 - ọ̀kẹ́ mẹ́wàá

1,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún / àádọ́ta ọ̀kẹ́ / egbélégbè[1]

10,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá / egbélégbè mẹ́wàá[1]

100,000,000 - ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún ọgọ́rùn / egbélégbè ọgọ́rùn[1]

1,000,000,000 - egbélégbèji

10,000,000,000 - egbélégbèta

100,000,000,000 - egbélégbèrin

1,000,000,000,000 - egbélégbàrun

10,000,000,000,000 - egbélégbèfa

100,000,000,000,000 - egbélégbèje

1,000,000,000,000,000 - egbélégbèjo

10,000,000,000,000,000 - egbélégbèsan

100,000,000,000,000,000 - egbélégbèwa

1,000,000,000,000,000,000 - egbélégbokonla

10,000,000,000,000,000,000 - egbélégbèjila

100,000,000,000,000,000,000 - egbélégbètala

1,000,000,000,000,000,000,000 - egbélégbarundinlogun[1]

tabi (infinity) - àìníye